Isaiah 30

Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín, òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín.

Isaiah 30:3 (UKJV) Therefore shall the strength of Pharaoh be your shame, and the trust in the shadow of Egypt your confusion.

1“Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,” ni Olúwa wí, “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;

2tí wọ́n lọ sí Ejibiti láìṣe fún mi, tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò, sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi.

3Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín, òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín.

4Bí àwọn olórí rẹ tilẹ̀ wà ní Ṣoani, tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hanisi,

5gbogbo wọn ni a ó dójútì, nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn, tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá, bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.