Isaiah 32

Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀ àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.

Isaiah 32:16 (UKJV) Then judgment shall dwell in the wilderness, and righteousness remain in the fruitful field.

14Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀, ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì; ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé, ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,

15títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá, àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràá àti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.

16Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀ àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.

17Èso òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà; àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.

18Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní ibùgbé àlàáfíà, ní ibùgbé ìdánilójú, ní àwọn ibi ìsinmi tí ó parọ́rọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.