Isaiah 32

Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́, ó ń gba èrò búburú láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà.

Isaiah 32:7 (UKJV) The instruments also of the churl are evil: he devises wicked devices to destroy the poor with lying words, even when the needy speaks right.

5A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́ tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn.

6Nítorí òmùgọ̀ sọ̀rọ̀ òmùgọ̀, ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi: òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀; ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo àti fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ ni ó mú omi kúrò.

7Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́, ó ń gba èrò búburú láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà.

8Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá àti nípa èrò rere ni yóò dúró.

9Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀, ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.