Isaiah 33

Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe; ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!

Isaiah 33:13 (UKJV) Hear, all of you that are far off, what I have done; and, all of you that are near, acknowledge my might.

11Ìwọ lóyún ìyàngbò, o sì bí koríko; èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.

12A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú; bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

13Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe; ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!

14Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni; ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́: “Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun? Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?”

15Ẹni tí ó ń rìn lódodo tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́, tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi,

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.