10“Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí. “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga, ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.
11Ìwọ lóyún ìyàngbò, o sì bí koríko; èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.
12A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú; bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”
13Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe; ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!
14Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni; ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́: “Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun? Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?”