Isaiah 33

“Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí. “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga, ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.

Isaiah 33:10 (UKJV) Now will I rise, says the LORD; now will I be exalted; now will I lift up myself.

8Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì, kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà. A ti ba àdéhùn jẹ́, a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí, a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.

9Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù, ojú ti Lebanoni ó sì sá Ṣaroni sì dàbí aginjù, àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn.

10“Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí. “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga, ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.

11Ìwọ lóyún ìyàngbò, o sì bí koríko; èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.

12A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú; bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.