Isaiah 33

Ìwọ lóyún ìyàngbò, o sì bí koríko; èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.

Isaiah 33:11 (UKJV) All of you shall conceive chaff, all of you shall bring forth stubble: your breath, as fire, shall devour you.

9Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù, ojú ti Lebanoni ó sì sá Ṣaroni sì dàbí aginjù, àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn.

10“Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí. “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga, ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.

11Ìwọ lóyún ìyàngbò, o sì bí koríko; èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.

12A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú; bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

13Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe; ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.