Isaiah 41

“Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọ ẹnìkan láti ìlà-oòrùn tí ó pe orúkọ mi. Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n, àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀.

Isaiah 41:25 (UKJV) I have raised up one from the north, and he shall come: from the rising of the sun shall he call upon my name: and he shall come upon princes as upon mortar, and as the potter treads clay.

23ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dání kí àwa kí ó lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín. Ẹ ṣe nǹkan kan, ìbá à ṣe rere tàbí búburú, tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa.

24Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko jásí nǹkan kan iṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun; ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra.

25“Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọ ẹnìkan láti ìlà-oòrùn tí ó pe orúkọ mi. Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n, àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀.

26Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí àwa kò bá fi mọ̀, tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé, ‘Òun sọ òtítọ́’? Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí, ẹnikẹ́ni kò sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.

27Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Wò ó, àwọn nìyìí!’ Mo fún Jerusalẹmu ní ìránṣẹ́ ìrò ìròyìn ayọ̀ kan.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.