1“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu, ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda, ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo,
2ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli— Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
3Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́, ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀; lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.
4Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó; àwọn iṣan ọrùn yín sì jẹ́ irin; bẹ́ẹ̀ ni iwájú yín idẹ ni.