Isaiah 56

Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí: “Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin

Isaiah 56:4 (UKJV) For thus says the LORD unto the eunuchs that keep my sabbaths, and choose the things that please me, and take hold of my covenant;

2Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí, àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin, tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

3Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀ mọ́ Olúwa sọ wí pé, “Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.” Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé, “Igi gbígbẹ lásán ni mí.”

4Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí: “Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin

5fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀ ìrántí kan àti orúkọ kan tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin, Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé tí a kì yóò ké kúrò.

6Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa láti sìn ín, láti fẹ́ orúkọ Olúwa àti láti foríbalẹ̀ fún un gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́ àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.