Isaiah 60

Gbogbo agbo ẹran ìlú Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ, àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́; wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi, bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.

Isaiah 60:7 (UKJV) All the flocks of Kedar shall be gathered together unto you, the rams of Nebaioth shall minister unto you: they shall come up with acceptance on mine altar, and I will glorify the house of my glory.

5Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán, ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀; ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ, sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.

6Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ, àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani. Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá, wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́ tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.

7Gbogbo agbo ẹran ìlú Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ, àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́; wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi, bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.

8“Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru, gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?

9Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí; ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi; mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn, pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn, fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.