Jeremiah 11

Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali.

Jeremiah 11:17 (UKJV) For the LORD of hosts, that planted you, has pronounced evil against you, for the evil of the house of Israel and of the house of Judah, which they have done against themselves to provoke me to anger in offering incense unto Baal.

15“Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi, bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè? Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀? Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀, nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.”

16Olúwa pè ọ́ ní igi olifi pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò.

17Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali.

18Nítorí Olúwa fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí.

19Mo ti dàbí ọ̀dọ́-àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa; n kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé: “Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀; jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè, kí a má lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.