Jeremiah 11

Nítorí Olúwa fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí.

Jeremiah 11:18 (UKJV) And the LORD has given me knowledge of it, and I know it: then you showed me their doings.

16Olúwa pè ọ́ ní igi olifi pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò.

17Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali.

18Nítorí Olúwa fi ọ̀tẹ̀ wọn hàn mí mo mọ̀ ọ́n; nítorí ní àsìkò náà ó fi ohun tí wọ́n ń ṣe hàn mí.

19Mo ti dàbí ọ̀dọ́-àgùntàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí a mú lọ fún pípa; n kò mọ̀ pé wọ́n ti gbìmọ̀ búburú sí mi wí pé: “Jẹ́ kí a run igi àti èso rẹ̀; jẹ́ kí a gé e kúrò ní orí ilẹ̀ alààyè, kí a má lè rántí orúkọ rẹ̀ mọ́.”

20Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, tí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo, tí ó ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀mí àti ọkàn, jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn; nítorí ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.