Jeremiah 14

Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni? Ṣé o ti ṣá Sioni tì? Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú tí a kò fi le wò wá sàn? A ń retí àlàáfíà ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá, ní àsìkò ìwòsàn ìpayà là ń rí.

Jeremiah 14:19 (UKJV) Have you utterly rejected Judah? has your soul loathed Zion? why have you smitten us, and there is no healing for us? we looked for peace, and there is no good; and for the time of healing, and behold trouble!

17“Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé: “ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé ní ọ̀sán àti ní òru láìdá; nítorí tí a ti ṣá wúńdíá, ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá pẹ̀lú lílù bolẹ̀.

18Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa. Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn. Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

19Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni? Ṣé o ti ṣá Sioni tì? Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú tí a kò fi le wò wá sàn? A ń retí àlàáfíà ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá, ní àsìkò ìwòsàn ìpayà là ń rí.

20Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa àti àìṣedéédéé àwọn baba wa; lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.

21Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa; má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀. Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá kí o má ṣe dà á.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.