Jeremiah 17

Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli; gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì. Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́n ti kọ Olúwa, orísun omi ìyè sílẹ̀.

Jeremiah 17:13 (UKJV) O LORD, the hope of Israel, all that forsake you shall be ashamed, and they that depart from me shall be written in the earth, because they have forsaken the LORD, the fountain of living waters.

11Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìṣòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.

12Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní ibi ilé mímọ́ wa.

13Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli; gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì. Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́n ti kọ Olúwa, orísun omi ìyè sílẹ̀.

14Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn, gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà, nítorí ìwọ ni ìyìn mi.

15Wọ́n sọ fún mi wí pé: “Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà? Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.” Ni Olúwa wí.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.