Jeremiah 17

Wọ́n sọ fún mi wí pé: “Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà? Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.” Ni Olúwa wí.

Jeremiah 17:15 (UKJV) Behold, they say unto me, Where is the word of the LORD? let it come now.

13Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli; gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì. Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́n ti kọ Olúwa, orísun omi ìyè sílẹ̀.

14Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn, gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà, nítorí ìwọ ni ìyìn mi.

15Wọ́n sọ fún mi wí pé: “Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà? Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.” Ni Olúwa wí.

16Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ, ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú. Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.

17Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi, ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.