Jeremiah 2

Àwọn kìnnìún ké ramúramù; wọ́n sì ń bú mọ́ wọn. Wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò; ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀.

Jeremiah 2:15 (UKJV) The young lions roared upon him, and yelled, and they made his land waste: his cities are burned without inhabitant.

13“Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì, wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi orísun omi ìyè, wọ́n sì ti ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró.

14Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí? Kí ló ha a dé tí ó fi di ìkógun?

15Àwọn kìnnìún ké ramúramù; wọ́n sì ń bú mọ́ wọn. Wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò; ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀.

16Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesi wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.

17Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí ara yín nípa kíkọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀ nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.