16Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesi wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.
17Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí ara yín nípa kíkọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀ nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
18Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti láti lọ mu omi ní Ṣihori? Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà?
19Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ nígbà tí o ti kọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀, ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
20“Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ; ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’ Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀ ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.