Jeremiah 23

Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sá pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan, kí èmi má ba a rí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi kò ha a kún ọ̀run àti ayé bí?” ni Olúwa wí.

Jeremiah 23:24 (UKJV) Can any hide himself in secret places that I shall not see him? says the LORD. Do not I fill heaven and earth? says the LORD.

22Ṣùgbọ́n ì bà ṣe pé wọn dúró nínú ìgbìmọ̀ mi, wọn ìbá ti kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ènìyàn mi. Wọn ìbá ti wàásù ọ̀rọ̀ mi fun àwọn ènìyàn wọn ìbá ti yípadà kúrò nínú ọ̀nà àti ìṣe búburú wọn.

23“Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí?” ni Olúwa wí, “kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jíjìn.

24Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sá pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan, kí èmi má ba a rí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi kò ha a kún ọ̀run àti ayé bí?” ni Olúwa wí.

25“Mo ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’

26Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀síwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìtànjẹ ọkàn wọn?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.