36Gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn, àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olórí agbo ẹran; nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run.
37Ibùgbé àlàáfíà yóò di ahoro, nítorí ìbínú ńlá Olúwa.
38Gẹ́gẹ́ bí kìnnìún yóò fi ibùba rẹ̀ sílẹ̀, ilẹ̀ wọn yóò sì di ahoro, nítorí idà àwọn aninilára, àti nítorí ìbínú ńlá Olúwa.