Jeremiah 3

Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti jẹ èso iṣẹ́ àwọn baba wa run, ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn, ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

Jeremiah 3:24 (UKJV) For shame has devoured the labour of our fathers from our youth; their flocks and their herds, their sons and their daughters.

22“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́, Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.” “Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.

23Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrúkèrúdò tí ó wà ní àwọn orí òkè kéékèèké àti àwọn òkè gíga, nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà Israẹli wà.

24Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti jẹ èso iṣẹ́ àwọn baba wa run, ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn, ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

25Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa, kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀. A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, àwa àti àwọn baba wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní a kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.