14Ìwọ Jerusalẹmu, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yè. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ?
15Ohùn kan sì ń kéde ní Dani o ń kókìkí ìparun láti orí òkè Efraimu wá.
16“Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀-èdè, kéde rẹ̀ fún Jerusalẹmu pé: ‘Ọmọ-ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìn wá wọ́n sì ń kígbe ogun láti dojúkọ ìlú Juda.
17Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá, nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ” ni Olúwa wí.
18“Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ ló fa èyí bá ọ ìjìyà rẹ sì nìyìí. Báwo ló ti ṣe korò tó! Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”