Jeremiah 4

Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?

Jeremiah 4:21 (UKJV) How long shall I see the standard, and hear the sound of the trumpet?

19Háà! Ìrora mi, ìrora mi! Mo yí nínú ìrora. Háà, ìrora ọkàn mi! Ọkàn mi lù kìkì nínú mi, n kò le è dákẹ́. Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè, mo sì ti gbọ́ igbe ogun.

20Ìparun ń gorí ìparun; gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparun lọ́gán ni a wó àwọn àgọ́ mi, tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan.

21Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?

22“Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi; wọn kò mọ̀ mí. Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ; wọ́n sì jẹ́ aláìlóye. Wọ́n mọ ibi ni ṣíṣe; wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”

23Mo bojú wo ayé, ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófo àti ní ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì ṣí.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.