21Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?
22“Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi; wọn kò mọ̀ mí. Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ; wọ́n sì jẹ́ aláìlóye. Wọ́n mọ ibi ni ṣíṣe; wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”
23Mo bojú wo ayé, ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófo àti ní ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì ṣí.
24Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n wárìrì; gbogbo òkè kéékèèké mì jẹ̀jẹ̀.
25Mo wò yíká n kò rí ẹnìkan; gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ló ti fò lọ.