Jeremiah 4

Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n wárìrì; gbogbo òkè kéékèèké mì jẹ̀jẹ̀.

Jeremiah 4:24 (UKJV) I beheld the mountains, and, lo, they trembled, and all the hills moved lightly.

22“Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi; wọn kò mọ̀ mí. Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ; wọ́n sì jẹ́ aláìlóye. Wọ́n mọ ibi ni ṣíṣe; wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”

23Mo bojú wo ayé, ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófo àti ní ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì ṣí.

24Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n wárìrì; gbogbo òkè kéékèèké mì jẹ̀jẹ̀.

25Mo wò yíká n kò rí ẹnìkan; gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ló ti fò lọ.

26Mo bojú wò, ilẹ̀ eléso, ó sì di aṣálẹ̀ gbogbo àwọn ìlú inú rẹ̀ sì ṣubú sínú ìparun níwájú Olúwa àti níwájú ríru ìbínú rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.