33Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò nínú ọgbà àjàrà àti oko Moabu. Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí; kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà, wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀.
34“Ohùn igbe wọn gòkè láti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi, láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi, nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ.
35Ní ti Moabu ni èmi yóò ti fi òpin sí ẹni tí ó rú ẹbọ ní ibí gíga àti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀,” ni Olúwa wí.
36“Nítorí náà ọkàn mi ró fún Moabu bí fèrè, ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti. Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé.
37Gbogbo orí ni yóò pá, gbogbo irùngbọ̀n ni a ó gé kúrò, gbogbo ọwọ́ ni a sá lọ́gbẹ́, àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́.