26Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
27“Èmi yóò fi iná sí odi Damasku, yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”
28Nípa ìlú Kedari àti ìjọba Hasori èyí ti Nebukadnessari ọba Babeli dojú ìjà kọ, èyí ni ohun tí Olúwa sọ, “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ ìlú Kedari, kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn run.
29Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọn ni wọn ó kó lọ; àgọ́ wọn yóò di ìṣínípò padà pẹ̀lú gbogbo ẹrù àti ìbákasẹ wọn. Àwọn ènìyàn yóò ké sórí wọ́n pé, ‘Ẹ̀rù yí káàkiri!’
30“Sálọ kíákíá! Fi ara pamọ́ sí ibi jíjìn, ẹ̀yin olùgbé Hasori,” ni Olúwa wí. “Nebukadnessari ọba Babeli ti dojú ìjà kọ ọ́.