Jeremiah 49

“Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akátá, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé, kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”

Jeremiah 49:33 (UKJV) And Hazor shall be a dwelling for dragons, and a desolation for ever: there shall no man abide there, nor any son of man dwell in it.

31“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú ìrọ̀rùn, èyí tí ó gbé ní àìléwu,” ní Olúwa wí. “Orílẹ̀-èdè tí kò ní odi tàbí irin, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń dágbé.

32Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun. Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́. Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,” báyìí ní Olúwa wí.

33“Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akátá, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé, kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”

34Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda.

35Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu, ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.