Jeremiah 49

Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda.

Jeremiah 49:34 (UKJV) The word of the LORD that came to Jeremiah the prophet against Elam in the beginning of the reign of Zedekiah king of Judah, saying,

32Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun. Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́. Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,” báyìí ní Olúwa wí.

33“Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn akátá, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé, kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”

34Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda.

35Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu, ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.

36Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé lòdì sí Elamu. Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin àti pé, kò sí orílẹ̀-èdè tí ilẹ̀ àjèjì Elamu kò ní lọ.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.