Jeremiah 49

“Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,” ni Olúwa wí.

Jeremiah 49:6 (UKJV) And afterward I will bring again the captivity of the children of Ammon, says the LORD.

4Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣògo nínú àfonífojì rẹ, ṣògo nínú àfonífojì rẹ fún èso? Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ammoni aláìṣòótọ́, ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé, ‘Ta ni yóò kò mí lójú?’

5Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,” ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

6“Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,” ni Olúwa wí.

7Nípa Edomu. Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?

8Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò, ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani, nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau, ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.