Jeremiah 5

Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ, ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn; wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,

Jeremiah 5:27 (UKJV) As a cage is full of birds, so are their houses full of deceit: therefore they are become great, and becoming rich.

25Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.

26“Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ, àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.

27Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ, ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn; wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,

28wọ́n sanra wọ́n sì ń dán. Ìwà búburú wọn kò sì lópin; wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀. Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.

29Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.