Jeremiah 5

Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

Jeremiah 5:29 (UKJV) Shall I not visit for these things? says the LORD: shall not my soul be avenged on such a nation as this?

27Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ, ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn; wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,

28wọ́n sanra wọ́n sì ń dán. Ìwà búburú wọn kò sì lópin; wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀. Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.

29Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

30“Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtara ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà.

31Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké, àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn, àwọn ènìyàn mi sì ní ìfẹ́ sí èyí, kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.