26Ẹ wá sórí rẹ̀ láti òpin gbogbo, sí ilé ìṣúra rẹ̀ sílẹ̀, ẹ kó o jọ bí òkìtì ọkà, kí ẹ sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ẹ má ṣe fí yòókù sílẹ̀ fún un.
27Pa gbogbo àwọn akọ màlúù rẹ, jẹ́ kí a kó wọn lọ ibi tí a ó ti pa wọ́n! Ègbé ní fún wọn! Nítorí ọjọ́ wọn dé, àkókò ìbẹ̀wò wọn.
28Gbọ́ ohùn àwọn tí ó sálọ, tí ó sì sálà láti Babeli wá, sì sọ ní Sioni, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san, ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.
29“Pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Babeli, ẹ dó tí ì yíkákiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà. Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ó ti ṣe, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, nítorí tí ó ti gbéraga sí Olúwa, sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.
30Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́,” ní Olúwa wí.