Jeremiah 50

Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́,” ní Olúwa wí.

Jeremiah 50:30 (UKJV) Therefore shall her young men fall in the streets, and all her men of war shall be cut off in that day, says the LORD.

28Gbọ́ ohùn àwọn tí ó sálọ, tí ó sì sálà láti Babeli wá, sì sọ ní Sioni, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san, ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀.

29“Pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Babeli, ẹ dó tí ì yíkákiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà. Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí ó ti ṣe, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ sí i, nítorí tí ó ti gbéraga sí Olúwa, sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.

30Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́,” ní Olúwa wí.

31“Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “nítorí ọjọ́ rẹ ti dé, àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò.

32Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde. Èmi yóò tan iná ní ìlú náà, èyí tí yóò sì jo run.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.