Jeremiah 50

Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde. Èmi yóò tan iná ní ìlú náà, èyí tí yóò sì jo run.”

Jeremiah 50:32 (UKJV) And the most proud shall stumble and fall, and none shall raise him up: and I will kindle a fire in his cities, and it shall devour all round about him.

30Nítorí náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ yóò ṣubú ní ìgboro, a ó sì pa àwọn ológun lẹ́nu mọ́,” ní Olúwa wí.

31“Wò ó, èmi yóò dojú kọ ọ́ ìwọ agbéraga,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “nítorí ọjọ́ rẹ ti dé, àkókò tí èmi ó bẹ̀ ọ wò.

32Onígbèéraga yóò kọsẹ̀, yóò sì ṣubú, kì yóò sì ṣí ẹni tí yóò gbé dìde. Èmi yóò tan iná ní ìlú náà, èyí tí yóò sì jo run.”

33Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: “A pọ́n àwọn ènìyàn Israẹli lójú àti àwọn ènìyàn Juda pẹ̀lú. Gbogbo àwọn tí ó kó wọn nígbèkùn dì wọn mú ṣinṣin wọn kò sì jẹ́ kí ó sá àsálà.

34Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, Olúwa Ọlọ́run Alágbára ni orúkọ rẹ̀. Yóò sì gbe ìjà wọn jà, kí ó ba à lè mú wọn wá sinmi ní ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Babeli.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.