Jeremiah 50

Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ. Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère, àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.

Jeremiah 50:38 (UKJV) A drought is upon her waters; and they shall be dried up: for it is the land of graven images, and they are mad upon their idols.

36Idà lórí àwọn wòlíì èké wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun, wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.

37Idà lórí àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ àti àwọn àjèjì nínú ẹgbẹ́ rẹ̀. Wọn yóò di obìnrin. Idà lórí àwọn ohun ìṣúra rẹ̀!

38Ilẹ̀ gbígbẹ lórí omi rẹ̀; yóò sì gbẹ. Nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ àwọn ère, àwọn ère tí yóò ya òmùgọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù.

39“Nítorí náà àwọn ẹranko ijù pẹ̀lú ọ̀wàwà ni yóò máa gbé ibẹ̀, abo ògòǹgò yóò sì máa gbé inú rẹ̀, a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́, láéláé, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ṣàtìpó nínú rẹ̀ láti ìrandíran.

40Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú agbègbè wọn,” ni Olúwa wí, “torí náà kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé ibẹ̀; ènìyàn ki yóò gbé nínú rè.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.