Jeremiah 51

Babeli yóò parun pátápátá, yóò sì di ihò àwọn akátá, ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé.

Jeremiah 51:37 (UKJV) And Babylon shall become heaps, a dwelling place for dragons, an astonishment, and an hissing, without an inhabitant.

35Kí gbogbo ìparun tí ó ṣe sí ẹran-ara wa wà lórí Babeli,” èyí tí àwọn ibùgbé Sioni wí. “Kí ẹ̀jẹ̀ wa wà lórí gbogbo àwọn tí ń gbé Babeli,” ni Jerusalẹmu wí.

36Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: “Wò ó, èmi yóò tì ọ́ lẹ́yìn lórí ohun tí o fẹ́ ṣe. Èmi ó sì gbẹ̀san, èmi yóò mú kí omi Òkun rẹ̀ àti orísun omi rẹ̀ gbẹ.

37Babeli yóò parun pátápátá, yóò sì di ihò àwọn akátá, ohun ẹ̀rù àti àbùkù, ibi tí ènìyàn kò gbé.

38Àwọn ènìyàn inú rẹ̀ bú ramúramù bí ọmọ kìnnìún.

39Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn wọn bá ru sókè, èmi yóò ṣe àsè fún wọn, èmi yóò jẹ́ kí wọn mutí yó tí wọn yóò máa kọ fun ẹ̀rín, lẹ́yìn náà, wọn yóò sun oorun, wọn kì yóò jí,” ni Olúwa wí.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.