41“Báwo ni Ṣeṣaki yóò ṣe dí mímú, ìfọ́nnu gbogbo àgbáyé. Irú ìpayà wo ni yóò bá Babeli láàrín àwọn orílẹ̀-èdè!
42Òkun yóò ru borí Babeli, gbogbo rírú rẹ̀ yóò borí Babeli.
43Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro, ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò.
44Èmi yóò fi ìyà jẹ Beli ti Babeli àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì. Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò jùmọ̀ sàn lọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́. Ní òótọ́ odi Babeli yóò sì wó.
45“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn mi! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Sá fún ìbínú ńlá Olúwa.