48Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn, yóò sì kọrin lórí Babeli: nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,” ni Olúwa wí.
49“Babiloni gbọdọ̀ ṣubú nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti a pa ní gbogbo ayé nítorí Babeli.
50Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró. Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè, ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.”
51“Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn: ìtìjú ti bò wá lójú nítorí àwọn àjèjì wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.”
52“Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò lórí àwọn ère fínfín rẹ̀, àti àwọn tí ó gbọgbẹ́ yóò sì máa kérora já gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.