Jeremiah 51

“Babiloni gbọdọ̀ ṣubú nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti a pa ní gbogbo ayé nítorí Babeli.

Jeremiah 51:49 (UKJV) As Babylon has caused the slain of Israel to fall, so at Babylon shall fall the slain of all the earth.

47Nítorí ìgbà náà yóò wá dandan nígbà tí èmi yóò fi ìyà jẹ àwọn òrìṣà Babeli; gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó dójútì gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀.

48Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn, yóò sì kọrin lórí Babeli: nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,” ni Olúwa wí.

49“Babiloni gbọdọ̀ ṣubú nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti a pa ní gbogbo ayé nítorí Babeli.

50Ẹ̀yin tí ó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ lọ, ẹ má dúró. Ẹ rántí Olúwa ní òkèrè, ẹ sì jẹ́ kí Jerusalẹmu wá sí ọkàn yín.”

51“Ojú tì wá, nítorí pé àwa ti gbọ́ ẹ̀gàn: ìtìjú ti bò wá lójú nítorí àwọn àjèjì wá sórí ohun mímọ́ ilé Olúwa.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.