Jeremiah 6

“Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán! Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.

Jeremiah 6:4 (UKJV) Prepare all of you war against her; arise, and let us go up at noon. Woe unto us! for the day goes away, for the shadows of the evening are stretched out.

2Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run, tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.

3Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n. Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká, olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”

4“Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun! Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán! Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán, ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.

5Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́ kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”

6Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀ kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká. Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò, nítorí pé ó kún fún ìninilára.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.