11Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí, ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.
12Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojúrere, ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.
13“Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ; èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.
14Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́ mi ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedéédéé mi jì.
15Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi! Bí mo bá sì ṣe ẹni rere, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè, èmi dààmú mo si wo ìpọ́njú mi.