17Ìwọ sì tún mu àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi di ọ̀tún ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi; àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun.
18“Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá? Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.
19Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè, à bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú.
20Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá! Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi. Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.
21Kí èmi kí ó tó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́, àní si ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú,