Jobu 10

Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá! Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi. Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.

Job 10:20 (UKJV) Are not my days few? cease then, and let me alone, that I may take comfort a little,

18“Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá? Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.

19Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè, à bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú.

20Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá! Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi. Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.

21Kí èmi kí ó tó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́, àní si ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú,

22ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkára rẹ̀, àti ti òjìji ikú àti rúdurùdu, níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.