16Bí mo bá gbé orí mi ga, ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìún àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.
17Ìwọ sì tún mu àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi di ọ̀tún ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi; àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun.
18“Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá? Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.
19Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè, à bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú.
20Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá! Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi. Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.