Jobu 15

“Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi; èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,

Job 15:17 (UKJV) I will show you, hear me; and that which I have seen I will declare;

15Kíyèsi i, bi Ọlọ́run ko ba gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀,

16mélòó mélòó ni ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérí, tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mu omi.

17“Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi; èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,

18ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn láti ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́.

19Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan, ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.