16mélòó mélòó ni ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérí, tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mu omi.
17“Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi; èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,
18ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn láti ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́.
19Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan, ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.
20Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.