1Ìgbà náà ní Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé,
2“Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán kí ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ nínú?
3Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?
4Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì, ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run.