30Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn; ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀, àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò.
31Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.
32A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.
33Yóò dàbí àjàrà tí a gbọn èso àìpọ́n rẹ̀ dànù, yóò sì rẹ̀ ìtànná rẹ̀ dànù bí i ti igi Olifi.
34Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.