3Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí; ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà.
4Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́, ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi.
5Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,
6kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
7“Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi; mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.